Oju mi ri ko to di pe mo gbaṣẹ iṣegun Ibile-Jasher Spritual

0
Oju mi ri ko to di pe mo gbaṣẹ iṣegun Ibile-Jasher Spritual

Oju mi ri ko to di pe mo gbaṣẹ iṣegun Ibile-Jasher Spritual

Oloye Ayọdeji Okunọla Babalọla, alaṣẹ ati oludasilẹ ileeṣẹ iṣegun ibilẹ ta a mọ si Jasher Spiritual, to wa niluu Ibadan ti sọ pe bo tilẹ jẹ pe ajogunba lati ọdọ baba oun niṣẹ naa, amọ kekere kọ ni nnkan toju oun ri ko to di pe oun gba lati ṣe e.

O sọrọ yii lakooko to n gba oniroyin wa lalejo ni ọfiisi ẹ niluu Ibadan. O sọ pe bi wọn ba sọ pe iṣe iṣegun ibilẹ loun yoo ma fi ṣe ọmọ araye loore, oun yoo sọ pe ki wọn tu itọ ẹ danu, ṣugbọn kadara ati ayanmọ ti duro de oun.

Oloye ọhun sọ pe iṣẹ iṣegun lọna iṣẹṣe, o ti wa ninu idile wọn, o ni baba oun naa tun jogun ẹ lọdọ baba to bi oun naa.

O fidi ẹ kalẹ pe nigba toun jade iwe mẹwaa oun tun tẹsiwaju ninu ẹkọ oun lọ sile iwe giga yunifasiti Ladoke Akintọla to wa ni Ogbomọṣọ, pẹlu abajade esi gidi.

Alaṣẹ Jasher Spiritual tun ṣalaye siwaju pe, “Igbe aye ki a ma jawe, gun ọṣẹ, ko wu mi, nigba naa gẹgẹ bi ẹni to ro pe oun kawe, ṣe ni mo n waṣẹ alakọwe lakooko naa.

“Mo ṣiṣẹ awọn alagbaṣe iyẹn kọngila ni Ekoo, mo tun ṣiṣẹ ni Chicken Republic, mi o ṣaa fẹẹ ṣiṣẹ yẹn.

“Nigba to tun ya mo pinnu lati da iṣẹ temi silẹ mo ni oko, mo gbin awọn ounjẹ ti ẹnu jẹ, ṣe lawọn Fulani yawọ ibẹ ti wọn dana sun un. Laimọ pe kadara ko le ta se.

Lẹyin naa ni ipenija loriṣii yọju, mo tun da ileeṣẹ ti wọn ti n ta gaasi silẹ bakan naa ni, loootọ latilẹ ni mo ti ni imọ lori tewetegbo nitori iṣẹ ti wọn fi tọ mi nileewee niyen.

Lẹyin eleyii ni ipe yẹn wa wa lori mi, gbogbo ibi ti mo ba de, wọn a ni iṣẹ to yẹ ki n ṣe mo fi silẹ, mi o ṣe e.

” Wọn ni mo ti fi iṣẹ ori silẹ. Mo waa ṣe iwadii, mo rin irinajo ibẹ ni mi ti pade awọn alawo ire ti wọn ni iṣẹ tawọn babanla mi ṣe, ni wọn pe mi fun.

O tun ṣalaye siwaju pe, “Mo jogun iṣẹ yii latọdọ baba to bi mi lọmọ, lati ọdun 1970 ni Jasher Spritual ti wa, a fi orukọ silẹ labẹ ijọba lọdun 1981.Orukọ ileeṣẹ wa, Baba mi lo fi pilẹ ẹ, aditu nla ni. Ko si pe meji.

Oloye Ayọdeji tun sọ pe, “Ni ileeṣẹ wa, Jasher Spritual, tewe tegbo ni Olodumare fi ran wa lati maa fi ṣe ọmọ araye looore., ka fi tu ide, ka fi ja ide.

“Ko si ẹni ti ẹ maa ri to n ṣe iṣẹṣe ti ko ni ja ewe ati egbo, ti ko nii to ori eku, ori ẹyẹ ati bẹẹbẹẹ lọ

“Gbogbo nnkan ni ọtun n de ba, gẹgẹ bi a ṣe mọ pe gbogbo igba ni nnkan yi pada, ki a ma ba rẹyin ninu aye ni a ṣe roo pe o yẹ, nitori awọn to wa ni oke okun tabi ilu to jinna, a ko le sọ pe ki wọn maa sare bọ nitori a fẹẹ wẹ ọṣẹ fun wọn.

“Laye atijọ, o digba ti wọn ba de ọdọ awọn baba wa, ki wọn ṣalaye nnkan to n ṣe wọn, ni wọn yoo to gbe igbesẹ. Ṣugbọn lode oni, irọrun ti n de ba ohun gbogbo.

“Gbogbo nnkan ta a ṣe fun iwosan nibi la ṣe e ni eyi ti ko nii gara lọ niwọntun niwọnsi.Bẹẹ lo ṣe fi ranṣẹ, to le lo oṣu mẹfa si ọdun kan ju bẹẹ lọ ti yoo fi maa ṣiṣẹ, ko ni si nnkan ti yoo ṣe.

“Ni ọna taa fi ṣe iwadii lori iṣẹṣe lati ti n ri awọn ọgbọn kọọkan, taa le ṣe nilana ibilẹ to si n ṣiṣẹ.

“Bi a ba ni ki a maa ka o le ni ẹgbẹrun kan iṣẹ iṣegun tileeṣẹ wa n gbe jade. Gbogbo aisan to jẹ mọ ti ti agọ ara ni Ọlọrun jogun fun wa nibi ta a wosan.

Oludasilẹ ọhun tun ba wa sọ ọpọ ọrọ nipa awọn nnkan tileeṣẹ wọn rọ mọ, eyi ti ẹ o ba pade ninu apa keji. Ẹ ku oju lọna

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

grandpashabetporno siteleripornoporno izleGrandpashabet Resmihttps://mail.pbidde.org/grandpashabetporno siteleriporno siteleriporno siteleriporno siteleriporno siteleriporno siteleriporno sitelerijojobetporno siteleriDeneme Bonusu Veren SitelerDeneme Bonusu Veren SitelerjojobetholiganbetEnbet girişporno siteleribetsatbetsatbetsathttps://tr.betsatyeniadresi.cam/jojobetholiganbet7711betsatporno siteleriDeneme Bonusu Veren Sitelerporno siteleriporno sitelerimarsbahiscasibomgrandpashabetholiganbetcasinolevantmarsbahisholiganbet girişholiganbetholiganbet girişpusulabetmarsbahis güncel girişmatbetmatbet girişsekabetgrandpashabetmatbetpusulabetvdcasinoimajbetpusulabetmatbetcasinolevantradissonbetbetgitbetgitmatbetgrandpashabetmarsbahiscasibomholiganbetcasibombetgaranticasinolevantcasinolevantcasinolevantcasinolevantcasibomcasibomcasinolevantjojobetjojobetgrandpashabetcasibomgrandpashabetholiganbetjojobetcratosroyalbetwbahisjojobetgrandpashabetcasibomgiftcardmall/mygiftgrandpashabetcasinolevantjojobet