Ẹ fọkanbalẹ idaniloju wa pe nnkan yoo pada bọ sipo- Oluwafẹmi Abiọdun-Oni

Bi gbogbo awọn ọmọ orileede yii ti n ṣajọyọ ayẹyẹ ọdun mẹrindinlaadọrin ọdun tilẹ wa, Naijiria, ti gbominira, Oludije fun ipo aṣofin agba niluu Abuja fun ẹkun Ogun Central, labẹ ẹgbẹ oṣelu ADC, Onimọ ẹrọ Samuel Oluwafẹmi Abiọdun-Oni, ti ni idaniloju wa pe nnkan yoo si pada bọ sipo rere laipẹ.
Ninu atẹjade ti oludije ọhun fọwọ si nibi to ti n ki awọn ọmọ orileede yii, ọmọ ipinlẹ Ogun ati paapaa aarin gbungbun Ogun, iyẹn Ogun Central ku ayẹyẹ ọdun ominira naa.
Bẹẹ lo kesi wọn pe ki wọn ma ṣe sọ ireti nu nitori gbogbo awọn ipenija ti wọn koju ni yoo di ohun igbagbe.
Abiọdun-Oni tun ṣalaye siwaju pe loootọ ni nnkan ko fi bẹẹ rọgbọ tawọn araalu n kigbe lọtun, ti wọn ki gbe losi lori bi ọrọ aje ṣe n dẹnukolẹ.
O ni oun mọ pe nipasẹ awẹ ati adura, orileede Naijiria yoo tubọ dagbasoke, ti gbogbo idojukọ akoko yii yoo di ohun itan.
Oludije labẹ ẹgbẹ oṣelu ADC, tun sọ pe,” Mo ki gbogbo awa ọmọ orileede yii ku ayẹyẹ ọdun kẹrindinlaadọrin ominira ta a ṣe lonii.
“Mo fẹẹ ki gbogbo wa lọ ni ifọkanbalẹ nitori idaniloju wa pe ayipada rere yoo de laipẹ yii, ẹ ma jẹ ka sọ ireti, nitori awọn ipenija wa ni yoo di ohun itan.
Bakan naa ni Abiọdun-Oni tun fi akoko yii rọ awọn araalu lati wa ni irẹpọ ati ifẹ pẹlu iṣọkan ki gbogbo ba le tẹ wọn lọwọ. O ni ki wọn rii pe alafia jọba laarin ilu.
O wa ran wọn let bi ibo ọdun 2027, ṣe n sunmọ ile, o ni ki wọn yẹra fawọn iwa jagidijagan to le da wahala silẹ, ki wọn ranti pe ẹbi kan naa ni gbogbo wọn.
Oludije aṣofin labẹ ẹgbẹ oṣelu ADC nipinlẹ Ogun wa rọ awọn eeyan agbegbe Ogun Central lapapọ lati fi ibo wọn gbe oun wọle.
O ni, ” Mo fẹẹ ki ẹ lo kaadi idibo yii lati fi gbe mi wọle gẹgẹ bi aṣoju yin niluu Abuja ninu ibo ọdun 2027.
“Gbogbo agbara ti Ọlọrun ba fun mi ni mo maa fi si yin ati pe mi o ni fi akoko yin ṣofo ti mo ba de ọhun. Lẹẹkan sii, mo ki gbogbo wa ku ti ayajọ ọdun ominira taa n ṣe lọwọ.


