Agnes Funshọ Akinlẹyẹ oludije ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun ko idaamu bawọn oludije yooku ni Ifọ keji

0
Agnes Funshọ Akinlẹyẹ oludije ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun ko idaamu bawọn oludije yooku ni Ifọ keji

Latigba ti Iroyin ti gba igboro pe Ọnarebu Agnes Funshọ Akinlẹyẹ, oludije fun ipo ọmọ ile igbimọ aṣofin nipinlẹ Ogun labẹ ẹgbẹ oṣelu NDC, fun ẹkun Ifọ keji, la gbọ pe jinnijinni ti n deba awọn ti wọn jọ n dije.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ṣe lawọn kan ti bẹrẹ si nii fimu finlẹ lati mọ iru eeyan ti oludije naa jẹ ti wọn ko si mọ ibi to fẹẹ gba yọ si wọn.

Ohun to tun wa ṣe pabanbari ni bawọn eeyan to wa ni Ifọ keji, ṣe n fojoojumọ darapọ mọ ẹgbẹ NDC ọhun ti wọn si tun fi atilẹyin wọn han si Ọnarebu naa.

Iwadii fi ye wa pe ere lọpọ awọn oloṣelu kan lagbegbe naa n sa kaakiri nitori bi ariwo Agness ṣe n fojoojumọ gbilẹ si.

Ṣugbọn ni bayii, Ọnarebu Funshọ ti wa sọ pe igbega ati idagbasoke yoo fi tubọ ba agbegbe toun ṣoju fun lo ṣe pataki foun.

Gẹgẹ bo ṣe wi, agbegbe Ifọ Keji kọja nnkan tawọn eeyan le foju bintin wo, idi niyi to fi jẹ pe ẹni to ba ṣoju wọn gbọdọ maa mu igbe aye irọrun bawọn olugbe to wa nibẹ.

O ni bo tilẹ jẹ pe iṣẹ awọn aṣofin ni lati ṣe awọn ofin to le inu awọn araalu dun ti wọn yoo fi mọ mudunmudun to wa ninu ijọba tiwa-n-tiwa.

Funshọ ṣalaye siwaju pe, “Loootọ ni mo jade lati dupo ọmọ ile igbimọ aṣofin nipinlẹ Ogun labẹ ẹgbẹ oṣelu NDC, eyi ti mo gbadura pe Ọlọrun yoo ran mi lọwọ lati debẹ gẹgẹ bi aṣoju rere fawọn eeyan mi.

“Ṣugbọn mo mu dawọn eeyan mi loju pe bi ilọsiwaju ati idagbasoke yoo ṣe de bawọn ni maa mu ni ọkunkundun.”

O ṣalaye pe ọpọ awọn eto loun ni fawọn eeyan Ifọ Keji ti yoo mu irọrun ba wọn, paapaa lati wa ọna abayọ sawọn iṣoro to n doju kọ wọn.

Oludije NDC ọhun wa lo akoko naa lati rọ awọn obinrin akẹgbẹ ẹ lati dide gbaruku ti oun lati le jawe olubori ninu ibo ọhun pẹlu ileri pe oun ko ni jawọn nitanmọ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

grandpashabetJojobetpusulabetpasacasinoJojobetJojobetcasibomholiganbetjojobet girişJojobetJojobetneredebahisslotrajojobetJojobetJojobetgrandpashabettürk ifşajojobetdeneme bonusu veren sitelerbahiscasinolunabetjojobetpusulabetvdcasinograndpashabetsekabetmatbetimajbetimajbetgrandpashabetgrandpashabetDeneme Bonusu Veren SitelerGrandpashabet ResmipusulabetkavbetsezarcasinojojobetjojobetkingroyalDeneme Bonusu Veren Siteler 2026grandpashabetpusulabetcasibomdeneme bonusu veren sitelerjojobet girişgrandpashabetgrandpashabetholiganbetholiganbetgrandpashabetgrandpashabetgrandpashabetgrandpashabetgrandpashabetgrandpashabetamgbahiscasibomcasibomcasibomgrandpashabetjojobetcasibomholiganbetholiganbetgrandpashabetholiganbetbetbey girişcasibomcasibombetgaranticashwingrandpashabet girişsekabet girişmatbetpusulabetimajbetpusulabetsekabet girişbettiltgrandpashabetgrandpashabetjojobetgrandpashabetcasibomgrandpashabetholiganbetholiganbet girişgrandpashabetgrandpashabetradissonbetholiganbet girişgrandpashabet girişpusulabet girişdoedadeneme bonusu veren siteler