Awọn eeyan agbegbe Ifọ keji fi atilẹyin wọn han si Azeez Babatunde gẹgẹ bi ọmọ ile igbimọ aṣofin

0
Awọn eeyan agbegbe Ifọ keji fi atilẹyin wọn han si Azeez Babatunde gẹgẹ bi ọmọ ile igbimọ aṣofin

Awọn eeyan agbegbe Ifọ keji fi atilẹyin wọn han si Azeez Babatunde gẹgẹ bi ọmọ ile igbimọ aṣofin

Pẹlu bi ipolongo ibo ṣe ti bẹrẹ bayii fun ibo gbogboogbo ti yoo waye lọdun 2027, awọn eeyan agbegbe Ifọ keji, nipinlẹ Ogun ti n fi atilẹyin wọn han si Ọnarebu Sadiq Azeez Babatunde,oludije ọmọ ile igbimọ aṣofin, labẹ ẹgbẹ oṣelu ADC.

Gẹgẹ iwadii wa, latigba ti wọn ti gbọ pe oludije ọhun jade ni wọn ti n gbaruku tii pe o kaju ẹ lati ṣoju wọn.

Ọpọ awọn to ba wa sọrọ sọ pe ko to di pe Azeez gbegba oṣelu lo ti jẹ ẹlẹyinju aanu, to n ṣe fawọn to wa lẹgbẹ ẹ.

A tun gbọ pe aimọye eeyan lo ti ti ara ẹ dide nipaṣẹ aanu to maa n ṣe ati pe wọn lo ni ọgbọn ati oye lati dari ilu bi wọn ba fi sipo adari.

Ṣugbọn ṣa, oludije ọhun naa ti sọrọ o ni kekere ni awọn eeyan ṣi n ri, bi wọn ba le fi ibo gbe oun wọle, oun ko nii doju ti wọn.

O sọ pe ẹgbẹ tawọn araalu n fẹ ti wọn mọ pe yoo mu atunṣe ba gbogbo iṣoro tawọn araalu dojukọ ni ADC, nitori ẹ ni wọn ṣe n duro ki idibo mi waye, ki wọn si fi ibo wọn le wọn danu.

O fikun ọrọ pe awọn eeyan ipinlè Ogun naa ti n mura silẹ pẹlu adura ti wọn si n gba ni pe ki ọdun to n bọ tete de.

O ṣalaye siwaju pe imọlẹ ẹgbẹ oṣelu ọhun ti tan kalẹ nibi gbogbo nipinlẹ Ogun titi to fi de awọn igberiko, eyi to mu kawọn araalu maa ṣatilẹyin fun wọn.

Oludije ọmọ ile igbimọ aṣofin naa tun ṣalaye pe ẹ o rii pe lọdun to kọja nibi ibo to waye lọdun 2023, ipo kẹta lawọn ṣe, ṣugbọn lakooko yii nibi ibo to n bọ, awọn ni yoo gbegba oroke.

Lori erongba ẹ lati di ọmọ ile igbimọ aṣofin, Sadiq Babatunde sọ pe oun dupẹ lọwọ Ọlọrun fun atilẹyin toun ri gba lati ọdọ awọn eeyan oun ni ẹkun Ifọ Keji.

O ṣalaye pe awọn eeyan ni wọn fẹ ki ayipada rere deba ijọba to wa lode yii, ti wọn si ti ṣetan lati fi kaadi idibo wọn le wọn jade.

Nitori ẹ ni wọn ṣe n fi ọkan oun balẹ pe awọn yoo rii pe wọn fi ibo wọn gbe e oun wọle.

O ṣalaye pe gbogbo nnkan to n jẹ afojusun oun lakooko yii ni bi irọrun, itẹsiwaju ati idagbasoke yoo ṣe deba awọn toun fẹẹ ṣoju fun, ti wọn ba dibo yan oun wọle.

O sọ pe awọn agbegbe kan wa ni Ifọ Keji, to jẹ pe inu inira ni wọn wa, idi ni pe gbogbo igba ni wọn maa sunkun sijọba lọrun lori ipo ti agbegbe wọn wa ṣugbọn ti wọn ko ri wọn ro, iru awọn bẹẹ ni mo maa kọkọ gbe igbesẹ le lori nile igbimọ aṣofin.

O tun ṣalaye siwaju pe eto ẹkọ, ilera fawọn araalu, imayedẹrun, ọrọ aje atawọn nnkan mii jẹ awọn opo pataki toun fẹẹ ṣiṣẹ le lori ati bi abo wọn yoo ṣe fẹsẹ rinlẹ.

O wa rọ awọn ara ipinlẹ Ogun lati dide atilẹyin fun ẹgbẹ ADC, ipinlẹ Ogun, fun ibo to n bọ, ki wọn si fi kaadi idibo wọn le APC wọgbo.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

grandpashabetPorno siteleripornoporno izleGrandpashabet Resmihttps://mail.pbidde.org/grandpashabetporno sitelerimarsbahiscasibomporno sitelerijojobet güncel girişporno siteleriporno siteleriporno sitelerijojobetDeneme Bonusu Veren SitelerGrandpashabetJojobet GirişPorno siteleriporno siteleriklasbahisporno siteleriporno siteleriDeneme BonusuDeneme Bonusu Veren Siteler 2026jojobetmarsbahisdeneme bonusubetgitporno sitelerijojobetgrandpashabetporno siteleriporno siteleriporno siteleriporno sitelerijojobetmarsbahisjojobetvdcasinosekabetpusulabettlcasinograndpashabet girişmarsbahis girişmarsbahismarsbahis girişjojobetvdcasino güncel girişimajbetsekabet girişpusulabetholiganbetpusulabet girişvdcasinoholiganbetmatadorbetbetgaranticasinolevantcashwinmercurecasinogameofbetcratosroyalbetbetgitmarsbahisholiganbetgrandpashabetcasibomjojobettipobetbahiscasinocasinomilyoncasinoroyalsuperbetinpalacebetradissonbetbetbeygrandpashabetcasibomjojobetjojobet girişholiganbetromabet1winbettiltbetciograndpashabetgrandpashabetjojobetcasinolevantcasinolevant