Eyiowuawi rọ gbogbo ọmọ Naijiria lati ni igbagbọ ati iduro ṣinṣin pẹlu ireti pe ADC yoo mu irọrun wa lọdun to n bọ

0
Eyiowuawi rọ gbogbo ọmọ Naijiria lati ni igbagbọ ati iduro ṣinṣin pẹlu ireti pe ADC yoo mu irọrun wa lọdun to n bọ

Eyiowuawi rọ gbogbo ọmọ Naijiria lati ni igbagbọ ati iduro ṣinṣin pẹlu ireti pe ADC yoo mu irọrun wa lọdun to n bọ

Ọnarebu Rasak Ọlasumbọ Eyiowuawi, oludije fun ipo aṣoju-ṣofin fun ẹkun Abẹokuta North, Ọbafẹmi Owode ari Ọdẹda, labẹ ẹgbẹ oṣelu ADC, nipinlẹ Ogun, ninu ibo ọdun 2027, ti rọ awọn ọmọ Naijiria lati ni igbagbọ ati iduro ṣinṣin pẹlu ireti pe ADC yoo mu irọrun wa lọdun to n bọ.

O sọrọ yii ninu iṣẹ to ran fun ti ikinni ku oriire fun ayẹyẹ ayajọ ọdun kẹrindinlaadọrin ti orileede wa gba ominira.

O sọ pe lakọkọ naa, o yẹ ki gbogbo wa dupẹ lọwọ Ọlọrun fun ore-ọfẹ to fun wa lati ri ayajọ ọdun naa layọ ati alaafia.

Bẹẹ lo sọ pe lagbara Ọlọrun nigba ti yoo ba fi di iwoyi ọdun to n bọ, orileede wa yoo ti maa dun, nitori eeyan wọn, igbakeji aarẹ wa tẹlẹ, Alaaji Abubakar Atiku yoo ti wa nipo aarẹ.

Oludije naa tun ṣalaye siwaju pe, “Atiku ti sọ fun wa pe bi oun ba de bẹ, nnkan to n da orileede wa laamu, oun yoo mu kuro, l
Lara ẹ ni afikun owo epo ti wọn yọ kuro, oun yoo daa pada.

“Bẹẹ naa lo ni oun yoo wa atunṣe si ọrọ eto abo. Mo rọ gbogbo ọmọ Naijiria lati jẹ ka ni igbagbọ ati iduro ṣinṣin laipẹ laijinna gbogbo nnkan yoo pada bọ sipo.

“Awa naa taa jẹ oludije oriṣiiriṣii nnkan la ni lọkan fawọn ọmọ Naijiria paapaa julọ awọn ọmọ ipinlẹ Ogun ati agbegbe wa.
A o rii pe gbogbo nnkan to jẹ ẹtọ atawọn iṣẹ akanṣe la maa ṣe fawọn ta n lo ṣojufun lakooko.

“Bi ẹ ba dibo fun wa ẹyin naa yoo ri iyatọ larin wa atawọn to ti wa nibẹ tẹlẹ. Naijiria
yoo lọsiwaju lakooko ti wa.

Eyiowuawi tun ṣalaye idi to tun ṣe jade dupo gẹgẹ bii aṣoju-ṣofin fun ẹkun Abẹokuta North, Ọbafẹmi Owode ati Ọdeda labẹ ẹgbẹ oṣelu ADC, O ni, “Gẹgẹ bi owe Yoruba to ni bi ẹṣin ba da ni, eeyan maa tun gun ni, awọn eeyan wa, mo nifẹẹ si wọn.

“Mo si rii pe awọn to wa nipo ọhun wọn ko to oju oṣuwọn to, nitori a ko ri nnkan ti wọn mu wale, a ko le ri wọn lori ijokoo.

“Ohun to n dun awọn eeyan wa lọkan, ẹni ti ko ba si nijokoo, wọn ko le sọ fun un, ko si ni le mu wa sile fun, nitori ẹ ni mo ṣe roo pe asiko ta a wa yii, a fi ki emi naa jade, ki n depo ọhun. Ki n le maa mu awọn nnkan mudunmudun ijọba tiwa-n-tiwa wa fawọn ti mo n ṣoju fun.

Nigba to n sọ nipa awọn nnkan to nii lọkan fawọn eeyan agbegbe ẹ to ba depo, Eyiowuawi sọ pe,” Awọn nnkan ti mo ni lọkan pọ, ẹ jẹ ka bẹrẹ latori eto agbẹ, awọn Yoruba sọ pe ti ebi ba kuro ninu ìṣẹ́, ìṣé bu ṣe.

“Mo ṣakiyesi pe Abẹokuta North, Ọbafẹmi Owode ati Ọdẹda, pupọ ninu wọn iṣẹ agbẹ ni wọn n ṣe, o lawọn eto tijọba funra wọn n ṣe,to yẹ ki a maa fi ran wọn lọwọ.

“Bi ẹ ba wo awọn ọna wa, ṣe lo ti ni loju, ẹ ẹ ẹ wo Ẹlẹga lasan, o ti wa nibẹ, o ti le lọdun mẹjọ, ọna ijọba apapọ ni,ko yẹ ko wa bo ṣe wa. O yẹ ki wọn ti pari ẹ.

“Bẹẹ naa ni ọna Adedọtun si Lafẹnwa si Agọọka, bakan naa lo ṣi wa. Nipa eto abo naa bi kii ba ṣawọn agbẹkọya atawọn fijilante, awọn lo mu duro ki i ṣe ijọba.

“Bi awa ba de ijọba, a o ṣeto bi wọn yoo ṣe maa fun wọn lowo, ki abo tunbọ fi le rinlẹ”

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

grandpashabetporno siteleripornoporno izleGrandpashabet Resmihttps://mail.pbidde.org/grandpashabetporno siteleriporno siteleriporno siteleriporno siteleriporno siteleriporno siteleriporno siteleripusulabetporno siteleriDeneme Bonusu Veren SitelerDeneme BonusuDeneme Bonusu Veren SitelerholiganbetBetpuan Girişporno sitelerimarsbahis güncel girişmarsbahismarsbahismarsbahisjojobetholiganbet7711marsbahisporno siteleriDeneme Bonusu Veren Sitelerporno siteleriporno sitelerigrandpashabetcasinolevantgrandpashabetcratosroyalbetvdcasinopusulabetcasinolevantmatbetmatbet girişmatbetsekabet girişpusulabetmarsbahis güncelpusulabet girişmatbet girişmarsbahisgrandpashabet girişholiganbetpusulabetmatbetgrandpashabetmarsbahisjojobetwbahiscasibom girişcasibomcasibomwbahisholiganbetcratosroyalbetcasibomjojobetcasibommarsbahismatbetgrandpashabetimajbetcasibomcasibomcasibomwbahisgrandpashabet güncel girişgrandpashabetgrandpashabetgrandpashabet güncel girişgrandpashabet girişholiganbetjojobetsekabetbetgitgrandpashabet girişgrandpashabetgrandpashabetgrandpashabet güncel girişgrandpashabetgrandpashabetgrandpashabetgiftcardmall/mygiftcasibomcasibomcasibomgrandpashabet girişcasibom