idagbasoke ilu Iroko lo jẹ mi logun lakooko yii- Oniroko

0
idagbasoke ilu Iroko lo jẹ mi logun lakooko yii- Oniroko

Oniroko tiluu Iroko, Ọba Oluṣẹgun Ayinde Feyijinmi, ti sọ pe ohun kan pataki to ṣe koko foun lakooko yii ni bi idagbasoke, itẹsiwaju ati ilọsiwaju yoo ṣe deba ilu toun jọba le lori.

 

O fesi ọrọ yii lati fi tan imọlẹ ti wọn lawọn kan sọ lati fi ba ilu jẹ, ki wọn si fi da rogbodiyan silẹ laarin ilu.

 

Ọba naa sọ pe irufẹ awọn eeyan bẹẹ ọta ilọsiwaju ni wọn, nitori gbogbo ẹni to ti n jokoo sidi ọtẹ, abosi ati dida wahala silẹ niluu ifẹ ilu ko si lọkan wọn.

 

O ni, “Ko le ma ri bẹẹ,ti nnkan ba n dun, to n dun, ti ko si ọta,alatako,ọlọtẹ, ẹ sọ fun onitọhun ko yẹra ẹ wo. Nitori eeyan ko le da a tan laye yii.

 

“Nnkan to ba ti dara, ọpọ eeyan lo maa n hu, amọ ọpọ kọ lọ tọ si,a ko le rin, ki ori maa mi. Bi mo ṣe wa niluu Iroko,ilu baba to bi baba mi ni.ti mo n wi bẹẹ, tawọn alaalẹ si n jẹ ko ri bẹẹ.eeyan ko le daa tan, iwọnba lo le ṣe.

 

” Kin ni mo tun n fẹ, mo n ri atilẹyin latọdọ ọpọ araalu, gbogbo awọn abinibi ọmọ Iroko, aafin ni wọn ti n ṣe ipade, gbogbo ẹgbẹ idagbasoke niluu yii ẹyin m ni wọn wa.

 

“Mo ti sọ laimọye igba pe ẹni tinu ba n bi ki wọn lọ si kootu, ki wọn si mu ẹri jade, titi di akoko yii to n lọ si ọdun kẹjọ ti mo gori oye, a ko ri ẹnikẹni, ko sẹni to nigboya.

 

” O waa ni bawo ni alejo kan yoo ṣe fẹẹ yi itan oun pada, wọn ko le mọ ọn to oun ati pe ija ilara lo n ba wọn ja, oun si fa wọn le Ọlọrun lọwọ.

Nigba ti Oniroko ṣalaye bo ṣe n ṣeto abo ilu ẹ, O sọ pe, ” Gbara ti mo ti gori itẹ awọn baba mi, ni mi o ti feto abo ṣere ṣere pẹlu awọn eeyan mi. Idi niyii taa fi kọ ileeṣẹ ọlọpaa.

 

“Bẹẹ ni a tun maa n ṣe ipade loorekoore pẹlu olori ẹgbẹ awọn agbegbe iyẹn CDA, awọn baalẹ,olori awọn Hausa ati Ibo ti wọn wa niluu lati le mọ ibi ti aabo duro de bẹẹ la st tun maa n forikori lati wa ọna abayọ sawọn ibi to ba ku diẹ kaato.

 

“Ohun taa si maa n jẹ ko ye wọn ni pe loootọ ọmọ Naijiria ni wa ṣugbọn a ko le gba ki ilu Iroko ba jẹ”

 

Ọba Feyijinmi iroko tun sọ pe, “Nigba tọrọ ijinigbe tun gbilẹ a pe awọn Hausa ati Ibo si ipade pe wọn gbọdọ fun wa ni olori kan, nitori ti nnkan ba ṣẹlẹ niluu oun ni wọn yoo lọ ba.

 

Laipẹ yii lo ni wọn fi ọkan lara awọn Hausa jẹ Ṣeriki, tawọn siwadii ẹ daadaa ko to di pe wọn fi joye.

 

Iyẹn nikan gbogbo awọn Hausa ati Ibo to wa niluu ni wọn ti gba fọọmu, ti wọn si ti buwọ luu gẹgẹ bi iwe adehun tawọn olori wọn si ti fọwọ si pẹlu.

 

 

Nigba ti Oniroko n sọ nipa ajọṣepọ to wa laarin oun ati Ọba Abdulkabir Adeyẹmi Ọbalanlẹgẹ, Ọlọta tiluu Ọta, o sọ pe bi Baba si ọmọ ni ajọṣepọ wọn ṣe danmọran ati pe awọn ti n murasilẹ fun ayẹyẹ ọjọọbi ọgọta ọdun Kabiyesi naa.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

pokerklasgrandpashabetJojobetbets10Casibomsuperbetindeneme bonusu veren sitelerpasacasinoJojobetjojobetcasibomgrandpashabetcasibomjojobet girişjojobetJojobetperabetjojobetholiganbetgrandpashabetholiganbetmarsbahisgrandpashabetpusulabeturfa konteynerşanlıurfa konteynervdcasinobettiltsuperbetin girişjojobetpusulabetpusulabetjokerbetjojobetjojobetJojobetGrandpashabetGrandpashabetgrandpashabet girişcasibomsekabet girişpusulabet girişVDCasinosuperbetinpusulabet güncel girişbetplaycasinomilyoncasinomilyonbetsalvadorteosbetbahiscasinoradissonbetholiganbetjojobetjojobetjojobetpornobahiscasinocasibommatbetsekabetimajbetpusulabetbetciosekabetjojobetmarsbahisholiganbetgrandpashabetimajbetteosbetonwin girişsahabet girişpornograndpashabetGrandpashabet Resmibets10betwoonjojobetperabetperabet girişperabet girişjojobetcasibomtipobetgrandpashabetjojobetjojobetholiganbetradissonbetbahiscasinoteosbetbetsalvadorcasinomilyonbetplaymercurecasinocasibomcasibomgrandpashabet girişcasibom girişcasibomgrandpashabet giriş