Ilu Odo nla ni Ibadan gbalejo lọjọ ti Oloye Okunlọla Ayọdeji Babalọla di Aarẹ Aṣipa.

Iṣẹ ati iwa rere ti eeyan maa n hu lawujọ lo jẹ ki wọn kawọn olori ilu maa fi wọn joye gẹgẹ bi owe Yoruba ksn to sọ pe iwa rere ni ẹṣọ eeyan.
Irufẹ nnkan bẹẹ ni wọn ro mọ Oloye Okunlọla Ayọdeji Babalọla, oludasilẹ ati alaṣẹ Jasher Spritual Production, ti wọn fi joye Aarẹ Aṣipa tilu Odo Ona nla, to wa ni Idi Ayunrẹ.
Ayẹyẹ oye ọhun to waye lawọn oloye ilu atawọn eeyan pataki niluu ti peju pesẹ lati fi ọla fun agba oniṣegun ibilẹ naa.
Nigba to n sọrọ lakooko ti Baalẹ ilu naa Oloye Emmanuel Bello fi joye tan, Oloye Ayọdeji dupẹ lọwọ Ọlọrun fun ayẹyẹ jijẹ oye ọhun.
O sọ pe pataki ni oye Aarẹ Aṣipa ti wọn fi oun jẹ, o si jẹ ọkan gboogi ninu oye ilu ọhun.
O ṣalaye siwaju pe Aṣipa jẹ ẹni to mọ ofin ati bi eto ilu yoo ṣe maa lọ laarin ilu. Nigba to n sọ nnkan ti wọn ri mọ ọn lara niluu naa, o sọ pe, ” Olorin kan kọrin pe iwa rere ni ẹṣọ ilu, iwa ati iṣẹ rere mi ni wọn wo mọ mi lara. Bẹẹ ni wọn tun wo bi mo ṣe n gbe iṣẹṣe larugẹ”
O tun ṣalaye siwaju pe lara iṣẹ akọkọ to wa niwaju oun lẹyin oyè toun jẹ ni bi idagbasoke yoo ṣe tubọ de ba ilu Odo nla, tawọn ohun rere yoo tubọ deba ilu.
O wa lo akoko naa lati fi dupẹ lọwọ Olubadan tiluu Ibadan, Ọba Rasheed Ladọja, bẹẹ lo tun dupẹ lọwọ Baalẹ ilu naa, Emmanuel Bello, fun bi wọn ṣe ro oye naa kan oun.
Bakan naa lo tun dupẹ lọwọ ẹbi ati ara ti wọn duro tii lọjọ naa. Ọjọ keji, to joye ni wọn wu oye naa lakooko ayẹyẹ Odo nla ti wọn ṣe.


