Ko si akọsilẹ buruku nipa Adekunle Adenuga oludije Gomina fẹgbẹ oṣelu BOOT nipinlẹ Ogun-Shobayọ 

0
Ko si akọsilẹ buruku nipa Adekunle Adenuga oludije Gomina fẹgbẹ oṣelu BOOT nipinlẹ Ogun-Shobayọ 

 

Alukoro fẹgbẹ oṣelu Because of our Tomorrow, iyẹn Nitori ọjọ iwaju wa, iyẹn BOOT, Ọnarebu Shobayọ Ọlasunkanmi Samuel Adeọla tọpọ mọ si SOSA, ti sọ pe kii ṣe awọn ṣadeede fa oludije Gomina wọn, Adekunle Adenuga kalẹ bi ko ṣe awọn tọpinpin ẹ daadaa tawọn si rii o koju oṣuwọn ati pe ẹni ti yoo fọ ipinlẹ Ogun mọ ni.

 

O sọrọ yii lakooko to n ba oniroyin sọrọ, o sọ pe gẹgẹ bi orukọ ẹgbẹ oṣelu wọn, Nitori ọjọ iwaju wa, bẹẹ lawọn gbọdọ ṣe nnkan ti yoo jẹ ko dara.

 

O ni Adekunle Adenuga ki i ṣe aṣiyan fawọn nitori awọn mọ pe o kaju ẹ.Shobayọ tun sọ pe, “Oludije Gomina wa jẹ akinkanju ati olootọ eeyan, awọn nnkan taa ri ta fi sọ pe wọn le jade dupo ẹgbẹ yii ni pe awa gan an ṣewadii ibi ti wọn ti n bọ, awọn iriri ati imọ ti wọn ti ni o fun wa ni koriya pe iru ẹni to le wa ọkọ ipinlẹ Ogun de ebute rere ni”.

 

Ọkunrin toun naa fẹẹ dije fun ipo ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun fun ẹkun Abẹokuta North tun fikun ọrọ ẹ pe oludije Gomina wọn ki i ṣe onijbiti ẹda tabi huwa ọdaran kan, o ni gbogbo akọsilẹ rẹ lo dara to si wu awọn.

 

Nigba to n sọ ibi ti wọn ba igbaradi wọn de, o sọ pe awọn ti gbinyanju nitori bawọn eeyan ṣe mọ pe o rọrun laisọ idakeji lati ko ẹgbẹ tuntun jọ. Ati lati taa ko to di pe wọn gba a lọwọ onitọhun.

 

O ni awọn ti tan kaakiri gbogbo ijọba ibilẹ nipinlẹ Ogun tawọn naa si ti n tan kalẹ kaakiri. Bẹẹ lo ni titi di akoko yii lawọn fi n ṣe ipolongo ẹgbẹ tawọn araalu si n tẹwọ gba.

 

O tun sọ pe oun ko ri ẹgbẹ APC , PDP, atawọn alatako yooku ro lati dena ẹgbẹ Nitori ọjọ iwaju wa, iyẹn Because of our Tomorrow, BOOT, fun ibo ọdun to n bọ.

 

O sọ pe PDP ati APC ti ṣe ijọba fọpọ ọdun lorileede yii ati nipinlẹ Ogun. Tawọn araalu ti ri ipa ti wọn ko ati nnkan ti wọn le ṣe.

 

O ni, “O ti da wa loju pe ko le si ayipada rere pẹlu oludije yoowu ti wọn ba mu wa, paapaa ọpọ wọn lo ti wa ninu ipo kan ri tẹlẹ.

 

“Fun idi eyi, ifọkanbalẹ waa pe awọn eeyan mọ iyatọ wọn si mọ eyi to dara ati pe anfaani wa fawọn araalu lati sọ pe awọn ṣetan lati yan ẹlomii.

 

” Ko si ibẹru kankan ti mo ni labẹ bo ti wu ki wọn maa pariwo tabi nawo to ẹgbẹ BOOT yoo fẹyin wọn janlẹ ninu ibo to n bọ”

 

Nigba to n sọ ibi ti wọn ba igbaradi wọn de, o sọ pe awọn ti gbinyanju nitori bawọn eeyan ṣe mọ pe o rọrun laisọ idakeji lati ko ẹgbẹ tuntun jọ. Ati lati taa ko to di pe wọn gba a lọwọ onitọhun.

 

O ni awọn ti tan kaakiri gbogbo ijọba ibilẹ nipinlẹ Ogun tawọn naa si ti n tan kalẹ kaakiri. Bẹẹ lo ni titi di akoko yii lawọn fi n ṣe ipolongo ẹgbẹ tawọn araalu si n tẹwọ gba.

 

Bakan naa lo gboriyin fun alaga ẹgbẹ naa nipinlẹ Ogun, Abiọdun Akerele fawọn ipa to n ko fun idagbasoke ati igbelarugẹ ẹgbẹ oṣelu BOOT.

 

O ṣapejuwe ẹ gẹgẹ bi ẹni to ni afojusun rere fun ọjọ iwaju ẹgbẹ oṣelu BOOT

 

Shobayọ tun sọ pe Akerele tun jẹ olufarajin, ti ko wa gbogbo nnkan mọ aya,to si jẹ olootọ eeyan, o ni ko fẹran ṣe ka ri mi.

 

Ọpọ ibi to wa ti wọn ba pe alaga wọn to jẹ pe awọn lo maa ran lọ sibẹ paapaa lori redio tabi tẹlifisan,, bẹẹ lo ni ajọṣepọ ati ifọwọsowọpọ to danmọran lo wa laarin gbogbo awọn tawọn jẹ oloye ẹgbẹ.

 

Ọkunrin yii wa fi ipinnu ẹ han lori bo ṣe jade dupo fun ọmọ ile igbimọ aṣofin fun ẹkun Abẹokuta North ninu ibo to n bọ naa

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

holiganbetgrandpashabetJojobetpusulabetsuperbetindeneme bonusu veren sitelerpasacasinoJojobetJojobetjojobetjojobet girişjojobetjojobet girişJojobetJojobetgrandpashabet girişholiganbetmatbetgrandpashabet girişholiganbet girişmatbetpusulabeturfa konteynerşanlıurfa konteynersuperbetinbetciobettiltBelugabahis giriş güncelpusulabetpusulabetjokerbetjojobetJojobetJojobetgrandpashabetdeneme bonusubettiltmatbet güncel girişsahabetsekabet girişpusulabet girişholiganbetholiganbetgrandpashabetgrandpashabetjojobetholiganbetgrandpashabetjojobetholiganbetgrandpashabetgrandpashabetjojobetstreameastbahiscasinoholiganbetgrandpashabetpusulabetvdcasinomatadorbetsahabetonwinmatadorbetsekabetmatbetimajbetgrandpashabetgrandpashabetgrandpashabetDeneme Bonusu Veren SitelerjojobetGrandpashabet Resmipusulabetkazandragrandpashabet girişgrandpashabet güncel girişjojobet güncel giriştipobetjojobet girişholiganbetgrandpashabetjojobetholiganbetgrandpashabetjojobetholiganbetgrandpashabetjojobetholiganbet girişibizabet girişibizabetgameofbet girişgameofbetesbetgrandpashabet girişbetbeygrandpashabetbetbey giriştambet giriştambet giriştambettambetwbahis girişDeneme Bonusu Veren Siteler 2026grandpashabetcasibompusulabetesbetcasibomwbahiscasibomcasibomgrandpashabetstreameastgrandpashabet güncel giriş