Ọrọ ti Iyabọ Ọbasanjọ sọ lori awọn ti wọn ki i ṣe oṣiṣẹ ijoba ti wọn gbowo oṣu oṣiṣẹ lakooko to wa ni kọmiṣanna ti da awuyewuye silẹ

0
Ọrọ ti Iyabọ Ọbasanjọ sọ lori awọn ti wọn ki i ṣe oṣiṣẹ ijoba ti wọn gbowo oṣu oṣiṣẹ lakooko to wa ni kọmiṣanna ti da awuyewuye silẹ

Lati igba ti Sẹnetọ Iyabọ Ọbasanjọ, to tun jade dupo naa fun ẹkun aarin gbungbun iyẹn Ogun Central, nile igbimọ aṣofin agba labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, ti sọrọ kan nibi eto ori redio niluu Abẹokuta, lawọn araalu ti n bu ẹnu atẹ luu pe iwa to hu ku diẹ kaato.

Ọrọ to sọ naa ni pe lakooko to wa nipo kọmiṣanna feto ilera nipinlẹ Ogun, oun maa n sanwo ijọba fawọn ti wọn kii ṣe oṣiṣẹ ijọba.

Gẹgẹ bo ṣe wi, “Mo tun fẹẹ sọ kinni kan fun yin, nigba ti mo wa nipo kọmiṣanna wọn gbe awọn orukọ kan wa ti wọn ki i ṣe oṣiṣẹ ijọba, ti wọn jẹ oloṣelu, ti wọn gbowo loṣooṣu.

“Wọn wa ba mi pe kinni kawọn ṣe fawọn eeyan naa, ṣe ki wọn daa owo naa duro, mo beere pe elo ni wọn fun wọn ati pe ṣe ọmọ bibi ipinlẹ Ogun ni wọn.

” Wọn ni ọmọ ipinlẹ Ogun ni wọn, nigba ti mo rii pe owo naa ko to nnkan ninu apo ijọba, mo ni ki wọn maa san lọ fun wọn ti wọn si n ṣe bẹẹ lọ.

Ṣugbọn oju tawọn araalu fi wo ọrọ naa ko dara, wọn ni ko yatọ si iwa jibiti, eyi to lodi si ofin ilẹ wa.

Ọkunrin kan, Ọgbẹni Ọlayiwọla Ibraheem lati Abẹokuta sọ pe oju ti Iyabọ Ọbasanjọ fi wo ọrọ naa loju toun bi ẹni pe o gbiyanju lati ka a mọ oore to ṣe fun araalu, amọ ko ri bẹẹ.

O ni ko tiẹ tọ si ẹni to fẹẹ dupo sẹnetọ lati tun le sọ iru nnkan bẹẹ sita pe wọn sanwo oṣiṣẹ ijọba fawọn ti wọn ki i ṣe oṣiṣẹ loṣoosu nigba naa.

O ni ka ni orileede waa yii ri bi a ṣe n fẹẹ, o yẹ ki wọn ti gbe obinrin yii lati ṣe iwadii finnifinni lee lori, nitori ko dara pupọ toun si mọ pe irufẹ awọn eeyan bẹẹ si wa nijọba ti wọn san iru owo bẹẹ titi di akoko yii.

Ẹnikan toun naa sọrọ to ni ka fi orukọ boun laṣiiri sọ ni tiẹ pe ka ni ilu oyinbo ni wọn ti ṣe iru nnkan bẹẹ ti wọn tun sọ ọ sita pẹlu igboya, ọgba ẹwọn ni wọn ko ba wa.

O ni kaka ti wọn yoo fi ma fawọn ti wọn ki i ṣe oṣiṣẹ lowo oṣu ijọba kilode ti wọn ko kuku gba wọn gẹgẹ bi oṣiṣẹ ti wọn yoo mọ owo iṣẹ wọn ni wọn gba.

Onitọhun nnkan to tọ to si yẹ ni pe ki Iyabọ Ọbasanjọ tọrọ aforiji fawọn iru aṣiṣe to ti ṣe yii, o ni iyẹn kii ṣe oore rara bikoṣe jibiti nla.

Lori ọrọ ti Iyabọ Ọbasanjọ to ti figba dupo gomina labẹ APC, ko to fẹgbẹ naa silẹ lọ si PDP fesi le nipa bi Yayi ti wọn fun ni tikẹẹti ggomina ṣe fẹsun kan an pe o ni koun da owo toun fi dije pada.

Awọn araalu sọ pe nigba ti Iyabọ Ọbasanjọ ti mọ pe ọwọ Yayi ko mọ, ko tiẹ yẹ ko baa jokoo papọ depodepo pe wọn yoo jọ sọrọ nipa owo rara.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

pokerklasgrandpashabetJojobetpusulabet girişsuperbetindeneme bonusu veren sitelerpasacasinoJojobetJojobetgrandpashabetjojobet girişgrandpashabetjojobet girişJojobetJojobetinterbahisjojobetgrandpashabetpusulabetgrandpashabet girişjojobet girişpusulabetmatbeturfa konteynerşanlıurfa konteynerimajbetsuperbetinbettiltbetciopusulabetpusulabetjokerbetjojobetJojobetJojobetjojobetGrandpashabet girişbettilt girişGrandpashabetgrandpashabet girişmatbet girişvdcasino girişpusulabet güncel girişpalacebetteosbetteosbetromabetgameofbetcratosroyalbetgrandpashabetholiganbetholiganbetjojobetbetparkbetparkjojobet girişDeneme Bonusu Veren SitelerbahiscasinoCratosroyalbetpusulabetsekabetmatbetvdcasinopalacebetbahiscasino1wingrandpashabetholiganbetjojobetimajbetgrandpashabetgrandpashabetgrandpashabetDeneme Bonusu Veren SitelerjojobetGrandpashabet Resmipusulabet girişkazandraperabet girişperabetperabet güncel girişjojobetcasibompulibetholiganbetgrandpashabetgrandpashabetpusulabetcasibomgrandpashabetgrandpashabetjojobetholiganbetgrandpashabetjojobetgrandpashabet girişgrandpashabet girişcasibombetpuanbetpuanholiganbet girişholiganbetibizabet girişibizabetteosbetholiganbet girişwbahiswbahis girişmercurecasinomercurecasino girişholiganbetholiganbet girişcasibomDeneme Bonusu Veren Sitelergrandpashabetcasibomcasibomcasibompusulabet giriş