Pataki lawọn obinrin ati ọdọ jẹ a ko gbọdọ fawọn sẹyin ninu oṣelu- Abiọdun-Oni Oludije fun ipo Sẹnetọ labẹ ADC Ogun.
.
Samuel Oluwafemi Abiodun-Oni, oludije fun ipo aṣofin agba niluu Abuja, fun ẹkun aarin gbungbun Ogun iyẹn Ogun Central, labẹ ẹgbẹ oṣelu ADC, ti sọ pe oun ko Sẹnetọ Iyabọ Ọbasanjọ gẹgẹ bi ẹni to fẹẹ dije fun ibo ọdun 2027.
Gẹgẹ bi alaye to ṣe, lo ti sọ pe, Emi o ri Anti Iyabọ Ọbasanjọ gẹgẹ bi ẹni to n dije, nitori ti eeyan ba sọ pe oun fẹran araalu, to lọ lati bi ọdun mẹẹẹdogun to lọ ti ko pada wẹyin wo, to waa de lakooko yii to loun tun fẹẹ jade dupo, iyooku ku sọwọ araalu.
ibeere to yẹ ki a maa beere lọwọ ẹ ni pe ṣe ifẹ araalu lo ni tabi tara ẹ,loootọ o ṣe daadaa fawọn akoko to lo, amọ ṣa, awọn Yoruba sọ pe taa ba ran ọmọ nileewe, to ṣe daadaa diẹ, ẹ jẹ ka tun ran ẹlomii lọ, iyẹn tun le ṣe daadaa julọ.
Ẹni to ti lọ lati ọdun kẹẹdogun to ṣẹṣẹ n beere nọmba foonu awọn to ti fi silẹ, ẹlomii to ba pe a sọ pe mo ṣẹṣẹ gba nọmba yin lọwọ lagbaja.
Iyẹn ku sọwọ araalu ati pe ibeere kan ti mo fẹẹ ki ẹ beere lọwọ ẹ ni pe ẹṣẹ wo ni mẹkunnu fi ṣẹ wọn ti wọn ko fẹẹ ki wọn gberi.
Baba ẹ ti ṣe aarẹ ọdun mẹjọ, oun naa tun ṣe aṣofin ọdun mẹrin, kin ni nnkan to gbagbe to n wa.
O ṣalaye siwaju si nipa Sẹnetọ Shuaib Salisu Afọlabi, to wa nile igbimọ aṣofin agba niluu Abuja, nibi to ti n ṣoju ẹkun Ogun Central pe bigba to kan lọọ fi akoko awọn to ṣoju fun sofo loun ka si, nitori oun fẹẹ ko wa tọka si awọn nnkan gidi to ṣe lati bii ọdun mẹta ataabọ to ti wa nibẹ.
Abiọdun-Oni tun fikun ọrọ ẹ pe, “Ẹ jẹ ka jọ bọ sigboro ka beere lọwọ araalu ọdun mẹrin to n ṣe lọọ yii, ko wa tọka sawọn nnkan to ṣe fun wọn.
Ipinnu mi fawọn araalu pọ, lakooko yii ko si ina, awọn eeyan ko sọrọ nipa iyẹn mọ, ka jade layọ, ka pada dele layọ ni wọn sọ, nitori abo, bẹẹ naa ko si ọna, laye ọjọun towo wọle fawọn ijọba ibilẹ, wọn a ṣe ọna lọ kaakiri abule, ko siyẹn mọ, ọna igboro nikan ni wọn n ṣe.
Eto wa fawọn ọdọ atawọn oṣiṣẹ fẹyinti, ko yẹ ki wọn ma la kaka ninu ile, bẹẹ ni eto tun wa fawọn akanda, mi o tiẹ ribi tijọba ti fọwọ ba wọn rara.
Aarin gbungbun Ogun n fẹ aṣoju gidi, ki i ṣe bi ti Salisu to fi akoko ọdun mẹrin ṣofo fawọn eeyan agbegbe naa ni, nitori emi funra mi, mi o rii nnkan to gbe ṣe fawọn araalu to ṣoju fun.
Ọrọ ẹnikan lo maa n jẹ irọ, ẹyin ẹ lọ sigbooro, ki ẹ beere lọwọ araalu.
O tun ṣalaye siwaju pe,” Ọrọ awọn obinrin wa ṣe pataki ninu oṣelu, nitori mo ranti igba kan ti mo lọọ ri Olu Falae, wọn ṣalaye kan fun wa bi wọn ṣe da peoples bank silẹ, ti iru nnkan bẹẹ naa wa ni ọkan mi, ki Ọlọrun fun wa ṣe, ti a ba ko obinrin ẹgbẹrun kan jọ, ti a da wọn lokoowo, ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un, ẹnikọọkan, ẹẹdẹgbẹta ninu wọn le maa mu dele bẹẹ ni a le ri mẹwaa to ma tipaṣẹ ẹ di olowo nla. iru eto bẹẹ bi a ba ṣe fawọn ọdọ a maa reyi to ma tipaṣẹ bẹẹ dide.
O wa lo anfaani ọhun lati gba awọn eeyan agbegbe Ogun Central lamọran pe ki wọn ma ni lọkan pe ibo tawọn di kọ ni wọn n ka, o loun fẹẹ fi gbogbo ẹnu sọ ọ pe oun ni wọn yoo ka.
O ni, “Ṣe ẹ ri awa araalu gan an la n fi aye jibiti silẹ, nibi tawọn igba eeyan ti forukọ silẹ kawọn bi ogun ba wa dibo, a ti fi aye ole silẹ fun wọn.
“Amọ nibi tawọn igba ti forukọ silẹ kawọn ọgọsan jade dibo nibẹ, ti wọn ba fẹẹ jale, ko le ju mẹwaa lọ, nitori ijọba to wa loke a fẹẹ lo ọwọ agbara.
“Ki awọn araalu ṣaanu ara wọn atawọn ọmọ wọn pẹlu.Ki wọn ye ta ọjọ ọla wọn fọdun mẹrin, ẹ wo nnkan to n ṣẹlẹ ni Ọṣun ti wọn fun wọn ni irẹsi kongo meji ati ẹgbẹrun marun un naira ti wọn si tun gbe wọn ṣepe ti wọn ko ba dibo fun wọn.
“Ṣe owo ati irẹsi yẹn ni wọn yoo fi ṣe ọna to yẹ ki wọn ṣe, ẹyin naa kuku mọ ibi ti wọn ba wa de, wọn a wa, wọn a tun parọ fun wa.
“Ẹ ma jẹ ka tori owo tabi irẹsi lọọ dibo, ki a dibo fun aṣoju to maa nifẹẹ wọn,


