Mo fẹẹ sin awọn eeyan mi lọna ti orukọ mi ko fi ni bajẹ-Ọnarebu Adeshina Jamiu

Oludije fun ipo ọmọ ile igbimọ aṣofin nipinlẹ Ogun labẹ ẹgbẹ oṣelu ADC fun agbegbe Ado Odo Ọta, Kin in ni, Ọnarebu Adeshina Adeọla Jamiu, ti mu da awọn eeyan ẹ loju pe erongba oun ni lati sin awọn eeyan ẹ ti wọn ba dibo yan an wọle lọna ti ko ni ba orukọ oun jẹ.
O sọrọ yii lakooko to n ba oniroyin sọrọ nipa ipinnu ẹ to ba wọle gẹgẹ bi aṣoju wọn, o sọ pe ọmọ agbegbe naa loun to si n gbe pẹlu wọn, nitori idi eyi gbogbo ipenija toun koju wọn loun yoo ṣiṣẹ le lori ti ọna abayọ yoo si wa pẹlu awọn iṣe akanṣe ti yoo mu idagbasoke wa.
Oludije naa sọ tọkantọkan pe ko si iye owo ti wọn fẹẹ le gbe kalẹ lati fi ra ẹtọ oun, nitori awọn to mọ oun latilẹ mọ nnkan toun le ṣe.
Ọnarebu Jamiu sọ pe, “Iru eeyan temi jẹ, ko si anfaani lati juwọ silẹ fẹnikankan, nitori pe tọkantọkan ni mo fẹẹ fi sin orileede ti Ọlọrun da mi si.
“Bi ẹ ba wo iru ẹgbẹ oṣelu ta a wa yii, a ki i ṣe ẹni to n ṣejọba lọwọ tabi ko owo ijọba fun, to ba jẹ tori owo ni, a o nii ṣe oṣelu ijọba ta a wa yii.Ṣugbọn nitori pe nnkan fojoojumọ bajẹ, a si fẹẹ sinlu, ko sẹni ti mo maa juwọ silẹ fun”.
Bakan naa lo sọ pe ẹgbẹ oṣelu APC tabi PDP, tawọn ti wọn jọ jade wa dije wa ko mu ibẹru tabi ifoya kankan wa ba oun, nitori pe awọn araalu ti mọ bi nnkan ṣe n lọ ati pe ọwọ wọn lo wa pẹlu.
O ni,” Dandan ni ki ọmọ ẹgbẹ mii jade nnkan ti wọn pe ni oṣelu niyẹn.A ni oludije APC ati PDP laarin wa.
“Bi a ba foju woo, iru awọn eeyan wo lo jade nibẹ, ko si ifoya tabi ibẹru fun mi, eyi to ku wa lọwọ araalu, ẹgbẹ ti wọn jade ko ni tumọ, awọn ti wọn si jade naa iru ẹkọ wo ni wọn ni, ohun to ṣe pataki fun mi ni lati lọọ sin araalu”.
Ọnarebu ọhun tun ṣalaye siwaju idi to fi ni lọkan lati jade dupo ọmọ ile igbimọ aṣofin, ipinlẹ Ogun, o sọ pe, “Ohun to mu mi lọkan ti mo fi fẹẹ jade dupo ni pe bi a ba wo bi ilu wa ṣe n lọọ yii, aisi nibẹ ni ai bawọn da si,a o si le wa nile, ki a sọ pe wọn ko ṣe daadaa.
“Ki awa naa lọ sibẹ, ki a mọ nnkan ti wọn ṣe nibẹ, ki lo faa ti ilu wa ṣe ri bi eleyii, nitori a ko ni ibomii ti a le salọ, ilu ti Ọlọrun jogun fun wa niyii.
“Ko bojumu, ki lo n faa, latigba tawọn ara iwaju ti n ṣe e lọ, ẹ wo bi wọn ṣe n ṣe gbogbo ẹ lo bajẹ, to n dojuru.
Bẹẹ ni ọkunrin yii tun mẹnu ba lara awọn nnkan to ni lọkan fawọn eeyan agbegbe ẹ bi wọn ba a dibo yan an wọle gẹgẹ bi aṣoju wọn.
O ni”Ero ọkan mi fun wọn ni lati mu ijọba de ọdọ wọn, ki wọn le mọ pe ijọba wa daadaa. Lati mu idagbasoke ba wọn, ko
si ka ri gbogbo mutumuwa, nitori pe oṣelu ti mo wa nibẹ, ki i ṣe fun ṣe ka ri mi bi ko ṣe olugbeja awọn eeyan mi.”
“Lara awọn nnkan ti mo fẹẹ mojuto lara ẹ ni ẹkọ, mo maa gbiyanju lati wa iṣẹ fawọn to ba ṣẹṣẹ jade nile ẹkọ bi agbara mi ba ṣe kaa. A maa mojuto awọn oniṣẹ ọwọ ati olokoowo lati ran wọn lọwọ pẹlu.
“Bẹẹ naa ni ilera tun ṣe pataki ni eyi to peye fun gbogbo awọn eeyan agbegbe mi. Mi o ni foju fo imọtoto ati idagbasoke rara.
“Gbogbo awọn ọna to ti bajẹ lawọn bii Ijoko, Sango, wọnu adugbo ni mọto ko ṣee gba kọja bẹẹ lo si jẹ pe ọpọ eeyan ni ọkada n gbe ṣubu.Awọn atunṣe wọn yii lo wa ninu ọkan mi. Ati pe bi nnkan ba ṣe n lọ, ni a o maa fi to araalu leti.
Ọnarebu Jamiu wa lo akoko naa lati fi kesi awọn to fẹẹ lọọ ṣoju lati awọn agbegbe biiỌta 1, Ọta 2, Ọta 3, Sango, Ijoko, Ilogbo, Iju ati Atan. Pe ki wọn rii pe wọn ti ni kaadi idibo wọn lọwọ, ki wọn si dibo foun gẹgẹ bi ọmọ ile igbimọ aṣofin wọn labẹ ẹgbẹ oṣelu ADC pẹlu ileri pe wọn ko nii kabamọ


