Ọba ilu Iroko dabira nla nibi ayẹyẹ ọdun iṣẹṣe to waye niluu na

Gbogbo ogunjọ, oṣu kẹjọ, ọdun ni ijọba fa kalẹ gẹgẹ bi ayajọ ọdun iṣẹṣe jakejado, idi niyii tijọba ipinlẹ Eko, Ogun ati Ọyọ, ṣe fi ọjọ naa silẹ fun isinmi fawọn oṣiṣẹ ijọba.
Bẹẹ lo ṣe niluu Iroko tawọn kan n pe ni abule Iroko, nipinlẹ Ogun, nibi ti wọn ti ṣayajọ ọdun naa.
Lati aago mẹfa idaji ni gbogbo awọn oniṣẹṣe ilu ọhun ti jade pẹlu asọ funfun lọrun, ninu eyi ti Oniroko tilu Iroko, Ọba Oluṣẹgun Ayinde Feyijinmi, ti ṣaaju wọn.
Odo kan ti wọn pe ni Ẹrukomu ni wọn kọkọ lọ nibi ti wọn ti lọọ ṣetutu fun ilu pẹlu igba aje, tilu ati ijo ni gbogbo ọmọ ilu fi de ọhun.
Ti wọn si tun gbadura pe ilu ọhun tubọ wa ni alaafia kawọn ohun idagbasoke tubọ maa wọlu.
Lẹyin ti wọn ṣe eyi tan ni wọn bẹrẹ si ni jo kaakiri ti wọn si n ya lawọn ile to jẹ orirun wọn atawọn ibi iṣẹmbaye ilu ọhun, ti wọn si n ṣadura fun wọn.
Pambabari ẹ nibi kan ti wọn pe ni oju alaalẹ ilu, iyẹn ibi ti wọn lawọn babanla wọn ti kọkọ tẹdo.
Nibẹ ni wọn tun ti ṣe awọn etutu loriṣiriṣi fun ilu ti wọn si fawọn alaalẹ ọhun lawọn nnkan ti wọn n fẹ lọdun yii.
Ninu ọrọ Ọba ilu naa, Ọba Oluṣẹgun Feyijinmi, Oniroko tilu Iroko, lo ti fi ẹmi imoore ẹ han bi awọn araalu ṣe tu jade lọjọ naa.
O dupẹ lọwọ ijọba lori bi wọn ṣe ka iṣẹṣe si fun wọn, o ni baba ẹni iṣẹṣe ni, iya ẹni iṣẹṣe ni, eegun ile ati ooṣa, iṣẹṣe lo pe wọn.
O ni awọn ẹbi ati ara lo wa bawọn ṣọdun naa.
O tẹṣiwaju pe, “Lati aarọ ọjọ naa lati bẹrẹ gẹgẹ bi iṣe wa, ki alaafia le wọlu, ki ohun rere tubọ ma lọ siwaju si niluu Iroko.
A ti wa dari pada si oju alaalẹ, nibi tawọn to da ilu yii silẹ ti kọkọ ṣẹ wa, nibẹ lati ṣadura fun wọn ti eegun si jade pẹlu. Ki
a to waa ṣe ayẹyẹ iwẹjẹ-wẹmu.
Lẹẹkan si, mo tun fi akoko yii dupẹ lọwọ ijọba fun anfaani ti wọn fun wa yii.
O waa gboriyin fun Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu lori bo ṣe faye gba iṣẹṣe laaye. O waa ni ọrọ naa ku sọwọ awọn gomina ilẹ Yoruba yooku ti wọn ko faye ọjọ isinmi silẹ bi awọn kan ṣe ṣee.
O ni nitori bi wọn ba n sọrọ iṣẹṣe ipinlẹ Ọṣun ko ṣee fọwọ rọ sẹyin paapaa nile Ifẹ, awọn gan an iṣẹṣe, ibẹ lo ti ṣẹ wa.
O tun wa rọ Aarẹ Bọla Ahmed ki wọn faye silẹ kaakiri orileede yii ki i ṣe Yoruba nikan ni wọn wa.
O ni nilẹ Hausa wọn ni iṣẹṣe ti wọn ṣe nibẹ ati nilẹ Ibo, boya ko tiẹ wọnu ofin ilẹ wa,kawọn aṣofin fọwọ si nitori a gbọdọ maa ranti wọn, a ko gbọdọ gbagbe ibi taa ti ṣẹ wa.
Nitori odo to ba gbagbe orisun, a o ni gbẹ, koda lawọn orileede bii Brazil,England, Argetina ati bẹẹ lọ, wọn ni bi wọn ṣe faye silẹ fun iṣẹṣe wọn.


