Wọn lo yẹ ki ajọ eleto idibo yọ orukọ Iyabọ Ọbasanjọ jade gẹgẹ bi oludije ipo senetọ fun agbegbe Ogun Central

Titi di akoko yii ọrọ wahala bi Sẹnetọ Iyabọ Ọbasanjọ ṣe jẹ oludije fẹgbẹ oṣelu PDP fun ẹkun Ogun Central si n mu awuyewuye da ni.
Gẹgẹ bi Iwadii oniroyin wa, laarin ọjọ kẹtalelogun si ọgbọnjọ, oṣu karun un ni ajọ eleto idibo INEC la silẹ pe ki ibo alabẹsekele waye ninu awọn ẹgbẹ oṣelu.
Ṣugbọn ninu oṣu kẹfa ni ẹgbẹ oṣelu PDP fa Iyabọ Ọbasanjọ kalẹ gẹgẹ bi oludije wọn fun ẹkun aarin gbungbun ipinlẹ Ogun iyẹn Ogun Central.
Lẹyin to fẹgbẹ oṣelu APC to ti dije fun ipo gomina silẹ. Ki i ṣe ibo pamari ni wọn fi muu gẹgẹ bi oludije gẹgẹ bi ajọ eleto idibo ṣe la a kalẹ fun wọn.
Iwadii wa tun tẹsiwaju pe Ọnarebu Ladi Adebutu nika lo si wẹ ara ẹ mọ gẹgẹ bi oludije Gomina,nitori titi di akoko taa n kọ iroyin yii ajọ eleto idibo ko tii gbe orukọ oludije aṣoju ṣofin ati ọmọ ile igbimọ fẹkun Ogun Central jade.
Wahala abẹnu to n waye ninu ẹgbẹ naa lapapọ eyi to jẹ ki wọn pin si igun tun jẹ ọkan lara gboogi to n mu idaamu ba wọn.
Idi niyii to fi jẹ pe lakooko ti ibo pamari waye, igun ọtọọtọ to wa ninu ẹgbẹ ọhun lo ṣe tiẹ lọtọ.
Ohun to si han kedere tawọn oloṣelu mẹnuba ni pe Iyabọ Ọbasanjọ ko kopa nibi ibo alabẹṣeke PDP ni Ogun.
Nitori pe ninu oṣu Kin in ni, ọdun yii lo darapọ mọ APC, to si kede pe oun fẹẹ dije dupo fun Gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu ọhun.
Nigba to di oṣu kẹrin ọdun ni APC, to wa nigba naa kede Sẹnetọ Ọlamilekan Adeọla Yayi, gẹgẹ bi oludije ti wọn mu amọ tinu Iyabọ Ọbasanjọ ko dun sii.
Ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu karun-un lo kọwe binu fi ẹgbẹ APC silẹ, to si darapọ mọ PDP, ninu oṣu kẹfa, nibi ti wọn ti gbe aṣia fun un gẹgẹ bi oludije fun ẹkun Ogun Central.
Bẹẹ la gbọ pe ko si akọsilẹ kankan pe wọb ṣe ibo pamari fun ipo sẹnetọ lọgbọnjọ, oṣu kẹrin ọdun yii.
Wọn lo si ti wa ninu ofin ajọ eleto idibo tọdun 2022, pe oludije to ba fẹẹ dije gbọfọ kopa nibi ibo pamari, to si jẹ pe awọn INEC ni yoo ṣe alamojuto ẹ, eyi ti wọn sọ pe PDP kuna lati ṣe ki wọn to mu ẹni to ti figba kan jẹ sẹnetọ ọhun.
Eyi lawọn oloṣelu kan fi sọ pe ti ajọ INEC ko ba fẹẹ gbe sẹyin ẹnikan ti wọn ba si fẹẹ ṣiṣẹ wọn bo ṣe tọ, ko yẹ ki orukọ Iyabọ Ọbasanjọ jade gẹgẹ bi oludije


