Abiọdun-Oni oludije fun ipo sẹnetọ fun aarin gbungbun Ogun bawọn oniṣẹṣe ṣajọyọ bẹẹ lo tun bẹbẹ fun atilẹyin wọn

Samuel Oluwafẹmi Abiọdun-Oni, oludije fun ipo Sẹnetọ fẹgbẹ oṣelu ADC fun ẹkun aarin gbungbun iyẹn Ogun Central, ti ki gbogbo awọn oniṣẹṣe jakejado ku ayẹyẹ ayajọ ọdun wọn ti wọn ṣe lonii.
Ninu atẹjade ti oludije naa fi sita lo ti bawọn oniṣẹṣe ọhun yọ pẹlu adura pe wọn yoo ṣe ọpọ ọdun.
O sọ pe pataki ni ọdun iṣẹṣẹ jẹ paapaa nilẹ Yoruba, eyi ti wọn fi maa ranti awọn alaalẹ atawọn oriṣa to tẹ ilu tabi agbegbe wọn do.
O ṣalaye ṣiwaju pe awọn Yoruba bọ, wọn a ni baba ẹni niṣẹṣe ẹni, iṣẹdalẹ ẹni ni Iṣẹṣe ẹni bẹẹ lo si jẹ ooṣa tun jẹ iṣẹẹṣe ẹni pẹlu.
O wa rọ awọn oniṣẹṣe jakejado ipinlẹ Ogun paapaa ni Ogun Central lati fi lo ọdun naa lati fi ṣetutu tabi adura si ilu ki idagbasoke tubọ fi le ba ipinlẹ wa.
O ni,” Mo ki gbogbo awọn oniṣẹṣe wa ku ayajọ ọdun ti wọn ṣe lonii, mo gba a ladura pe awọn etutu ti ẹ ba ṣe lonii yoo ṣe tẹwọgba de ọdọ Olodumare.
” Bẹẹ ni mo tun rọ yin ki ẹ jẹ ki alaafia, iṣọkan ati ifẹ ko jọba laarin, gbogbo awọn etutu to ba si yẹ ti yoo le mu ki idagbasoke ba ipinlẹ Ogun ati orileede yii lapapọ ni ki ẹ ṣe, ki Eledumare si tẹwọgba.
Abiọdun-Oni ṣalaye siwaju pe gẹgẹ bi wọn ṣe mọ pe akoko ibo sunmọ etile, ki wọn lo akoko ọdun ti wọn ṣe latigba adura pe ki Ọlọrun gbakoso kijọba tuntun le wọle lọdun 2027.
O ki wọn ṣatilẹyin fun ẹgbẹ oṣelu ADC lati gba akoso, ki wọn si jumọ fọwọsowọpọ gbe oun wọle fun ipo aṣofin niluu Abuja fun ẹkun Ogun Central.
O ṣalaye pe gbogbo wa la mọ nnkan to n waye ni aarin gbungbun fawọn to ti ṣoju wọn, eyi to ni wọn kan fi akoko wọn ṣofọ, pẹlu idaniloju pe toun ko ni ribẹ, bi wọn ba gbe oun wọle lọdun 2027.
O wa pari ọrọ ẹ pe ajọṣepọ to danmọran yoo wa laarin oun ati gbogbo awọn eeyan Ogun Cental lapapọ.


